Òwe 23:32
Proverbs 23:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.
Proverbs 23:32 in English
Proverbs 23:32 · Berean Standard Bible
In the end it bites like a snake and stings like a viper.
Context
30Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì;
àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò. 31Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n,
nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,
tí a gbé e mì, tí ó ń dùn. 32Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò,
a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀. 33Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin,
àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà. 34Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárín Òkun,
tàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.