Òwe 22:4
Proverbs 22:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
Proverbs 22:4 in English
Proverbs 22:4 · Berean Standard Bible
The rewards of humility and the fear of the LORD are wealth and honor and life.
Context
2Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀:
Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn. 3Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,
ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:
ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà. 4Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè. 5Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:
ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn. 6Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:
nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.