Native Bible

Proverbs 22:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.

Proverbs 22:3 in English

Proverbs 22:3 · Berean Standard Bible

The prudent see danger and take cover, but the simple keep going and suffer the consequences.

Context

1Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ. 2Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀: Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn. 3Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà. 4Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè. 5Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà: ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.