Òwe 21:23
Proverbs 21:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́, ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.
Proverbs 21:23 in English
Proverbs 21:23 · Berean Standard Bible
He who guards his mouth and tongue keeps his soul from distress.
Context
21Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,
òdodo, àti ọlá. 22Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára,
ó sì bi ibi gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú. 23Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́,
ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu. 24Agbéraga àti alágídí ènìyàn ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀,
àti nínú ìbínú púpọ̀púpọ̀. 25Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé;
nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.