Native Bible

Proverbs 20:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké. Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Proverbs 20:23 in English

Proverbs 20:23 · Berean Standard Bible

Unequal weights are detestable to the LORD, and dishonest scales are no good.

Context

21Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín. 22Má ṣe wí pé, “N ó sẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ.” Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là. 23Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké. Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn. 24Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn. Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni? 25Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.