Òwe 19:12
Proverbs 19:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún, ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.
Proverbs 19:12 in English
Proverbs 19:12 · Berean Standard Bible
A king’s rage is like the roar of a lion, but his favor is like dew on the grass.
Context
10Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá,
mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé. 11Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù;
fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá. 12Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún,
ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko. 13Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,
aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò. 14A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí,
ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.