Native Bible

Proverbs 19:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

Proverbs 19:13 in English

Proverbs 19:13 · Berean Standard Bible

A foolish son is his father’s ruin, and a quarrelsome wife is like a constant dripping.

Context

11Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù; fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá. 12Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún, ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko. 13Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò. 14A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí, ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni. 15Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn, ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.