Òwe 17:16
Proverbs 17:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè, níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n?
Proverbs 17:16 in English
Proverbs 17:16 · Berean Standard Bible
Why should the fool have money in his hand with no intention of buying wisdom?
Context
14Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi;
nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà. 15Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi,
Olúwa kórìíra méjèèjì. 16Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè,
níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n? 17Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,
arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú. 18Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra,
ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.