Native Bible

Proverbs 17:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

Proverbs 17:12 in English

Proverbs 17:12 · Berean Standard Bible

It is better to meet a bear robbed of her cubs than a fool in his folly.

Context

10Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀. 11Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe, ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i. 12Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. 13Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre, ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé. 14Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi; nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.