Native Bible

Proverbs 14:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora; ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.

Proverbs 14:13 in English

Proverbs 14:13 · Berean Standard Bible

Even in laughter the heart may ache, and joy may end in sorrow.

Context

11A ó pa ilé ènìyàn búburú run, ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i. 12Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú. 13Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora; ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́. 14A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀, ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀. 15Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.