Òwe 12:5
Proverbs 12:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èrò àwọn olódodo tọ́, ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.
Proverbs 12:5 in English
Proverbs 12:5 · Berean Standard Bible
The plans of the righteous are just, but the counsel of the wicked leads to deceit.
Context
3A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú
ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu. 4Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀
ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà. 5Èrò àwọn olódodo tọ́,
ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn. 6Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là. 7A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;
ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.