Native Bible

Proverbs 11:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.

Proverbs 11:26 in English

Proverbs 11:26 · Berean Standard Bible

The people will curse the hoarder of grain, but blessing will crown the one who sells it.

Context

24Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní. 25Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i; ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura. 26Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà. 27Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi. 28Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú; ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.