Native Bible

Philippians 4:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

Philippians 4:13 in English

Philippians 4:13 · Berean Standard Bible

I can do all things through Christ who gives me strength.*

Context

11Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. 12Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. 13Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi. 14Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi. 15Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.