Filemoni 1:13
Philemon 1:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìyìnrere
Philemon 1:13 in English
Philemon 1:13 · Berean Standard Bible
I would have liked to keep him with me, so that on your behalf he could minister to me in my chains for the gospel.
Context
11Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá. 12Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. 13Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìyìnrere 14ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe. 15Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.