Native Bible

Numbers 8:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni kí o mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa, gbogbo ọmọ Israẹli yóò sì gbọ́wọ́ lé àwọn ọmọ Lefi lórí.

Numbers 8:10 in English

Numbers 8:10 · Berean Standard Bible

You are to present the Levites before the LORD and have the Israelites lay their hands upon them.

Context

8Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 9Ìwọ ó sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àpapọ̀ ọmọ Israẹli jọ síbẹ̀ pẹ̀lú. 10Báyìí ni kí o mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa, gbogbo ọmọ Israẹli yóò sì gbọ́wọ́ lé àwọn ọmọ Lefi lórí. 11Aaroni yóò sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wá, kí wọn lè máa ṣiṣẹ́ Olúwa. 12“Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.