Native Bible

Numbers 4:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kohati kúrò lára àwọn ọmọ Lefi.

Numbers 4:18 in English

Numbers 4:18 · Berean Standard Bible

“Do not allow the Kohathite tribal clans to be cut off from among the Levites.

Context

16“Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí. Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.” 17Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 18“Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kohati kúrò lára àwọn ọmọ Lefi. 19Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má ba à kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálùkù àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé. 20Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kohati kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.