Numeri 4:17
Numbers 4:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
Numbers 4:17 in English
Numbers 4:17 · Berean Standard Bible
Then the LORD said to Moses and Aaron,
Context
15“Lẹ́yìn tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀síwájú, kí àwọn ọmọ Kohati bọ́ síwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kohati ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ ìpàdé. 16“Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí. Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.” 17Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 18“Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kohati kúrò lára àwọn ọmọ Lefi. 19Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má ba à kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálùkù àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.