Numeri 36:1
Numbers 36:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn olórí ìdílé Gileadi, ọmọkùnrin Makiri ọmọ Manase tí ó wá láti ara ìdílé ìran Josẹfu wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mose àti àwọn olórí, àwọn ìdílé Israẹli.
Numbers 36:1 in English
Numbers 36:1 · Berean Standard Bible
Now the family heads of the clan of Gilead son of Machir son of Manasseh, one of the clans of Joseph, approached Moses and the leaders who were the heads of the Israelite families and addressed them,
Context
1Àwọn olórí ìdílé Gileadi, ọmọkùnrin Makiri ọmọ Manase tí ó wá láti ara ìdílé ìran Josẹfu wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mose àti àwọn olórí, àwọn ìdílé Israẹli. 2Wọ́n sọ pé, “Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́. Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Selofehadi arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. 3Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Israẹli mìíràn; nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbà á kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.