Numeri 36:2
Numbers 36:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sọ pé, “Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́. Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Selofehadi arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.
Numbers 36:2 in English
Numbers 36:2 · Berean Standard Bible
saying, “When the LORD commanded my lord to give the land as an inheritance to the Israelites by lot, He also commanded him to give the inheritance of our brother Zelophehad to his daughters.
Context
1Àwọn olórí ìdílé Gileadi, ọmọkùnrin Makiri ọmọ Manase tí ó wá láti ara ìdílé ìran Josẹfu wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mose àti àwọn olórí, àwọn ìdílé Israẹli. 2Wọ́n sọ pé, “Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́. Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Selofehadi arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. 3Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Israẹli mìíràn; nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbà á kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa. 4Nígbà tí ọdún ìdásílẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ baba ńlá wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.