Numeri 32:15
Numbers 32:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tí ẹ̀yin bá yípadà ní ẹ̀yìn rẹ̀ yóò sì fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí sílẹ̀ ní aginjù, ìwọ yóò sì mú un ṣe ìparun.”
Numbers 32:15 in English
Numbers 32:15 · Berean Standard Bible
For if you turn away from following Him, He will once again leave this people in the wilderness, and you will be the cause of their destruction.”
Context
13Ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli ó sì mú wọn rìn ní aginjù fún ogójì ọdún, títí tí àwọn ìran tí wọ́n ṣe búburú ní ojú rẹ̀ fi lọ. 14“Níbí ni ẹ̀yin wà, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀yin dìde ní ipò baba yín, ẹ sì jẹ́ kí ìbínú gbígbóná Olúwa ru sí Israẹli. 15Tí ẹ̀yin bá yípadà ní ẹ̀yìn rẹ̀ yóò sì fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí sílẹ̀ ní aginjù, ìwọ yóò sì mú un ṣe ìparun.” 16Nígbà náà wọ́n wá sí òkè ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, “Àwa yóò fẹ́ láti kọ́ ilé ẹran níhìn-ín yìí fún ohun ọ̀sìn wa, àti ìlú fún àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa. 17Ṣùgbọ́n àwa ṣetán láti dira ogun ṣáájú àwọn ọmọ Israẹli títí tí a yóò fi mú wọn dé ọ̀dọ̀ wọn lákokò yìí, àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa yóò gbé inú ìlú tí a mọ odi sí fún ìdáàbòbò wọn lọ́wọ́ olùgbé ilẹ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.