Native Bible

Numbers 32:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli ó sì mú wọn rìn ní aginjù fún ogójì ọdún, títí tí àwọn ìran tí wọ́n ṣe búburú ní ojú rẹ̀ fi lọ.

Numbers 32:13 in English

Numbers 32:13 · Berean Standard Bible

The anger of the LORD burned against Israel, and He made them wander in the wilderness forty years, until the whole generation who had done evil in His sight was gone.

Context

11‘Nítorí wọn kò tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó gòkè láti Ejibiti ni yóò rí ilẹ̀ tí mo pinnu gẹ́gẹ́ bí ìbúra fún Abrahamu, fún Isaaki àti fún Jakọbu: 12kò sí ẹnìkankan àyàfi Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissiti àti Joṣua ọmọ Nuni, nítorí wọ́n tẹ̀lé Olúwa tọkàntọkàn.’ 13Ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli ó sì mú wọn rìn ní aginjù fún ogójì ọdún, títí tí àwọn ìran tí wọ́n ṣe búburú ní ojú rẹ̀ fi lọ. 14“Níbí ni ẹ̀yin wà, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀yin dìde ní ipò baba yín, ẹ sì jẹ́ kí ìbínú gbígbóná Olúwa ru sí Israẹli. 15Tí ẹ̀yin bá yípadà ní ẹ̀yìn rẹ̀ yóò sì fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí sílẹ̀ ní aginjù, ìwọ yóò sì mú un ṣe ìparun.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.