Numeri 31:47
Numbers 31:47 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Israẹli, Mose yan ọ̀kan lára àádọ́ta ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.
Numbers 31:47 in English
Numbers 31:47 · Berean Standard Bible
From the Israelites’ half, Moses took one out of every fifty persons and animals and gave them to the Levites who kept charge of the tabernacle of the LORD, as the LORD had commanded him.
Context
45tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (30,500). 46Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ (16,000). 47Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Israẹli, Mose yan ọ̀kan lára àádọ́ta ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa. 48Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wá sọ́dọ̀ Mose. 49Wọ́n sì sọ fún un pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ-ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan tó dín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.