Numeri 31:49
Numbers 31:49 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì sọ fún un pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ-ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan tó dín.
Numbers 31:49 in English
Numbers 31:49 · Berean Standard Bible
and said, “Your servants have counted the soldiers under our command, and not one of us is missing.
Context
47Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Israẹli, Mose yan ọ̀kan lára àádọ́ta ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa. 48Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wá sọ́dọ̀ Mose. 49Wọ́n sì sọ fún un pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ-ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan tó dín. 50Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka-àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú Olúwa.” 51Mose àti Eleasari àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.