Native Bible

Numbers 31:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mose, Eleasari àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbèríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó.

Numbers 31:13 in English

Numbers 31:13 · Berean Standard Bible

And Moses, Eleazar the priest, and all the leaders of the congregation went to meet them outside the camp.

Context

11Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran. 12Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mose àti Eleasari àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Israẹli ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani létí Jeriko. 13Mose, Eleasari àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbèríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó. 14Inú bí Mose sí àwọn olórí ọmọ-ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún tí wọ́n ti ogun dé. 15Mose sì béèrè wí pé, “Ẹ̀yin ha dá gbogbo àwọn obìnrin sí bí?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.