Native Bible

Numbers 31:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran.

Numbers 31:11 in English

Numbers 31:11 · Berean Standard Bible

and carried away all the plunder and spoils, both people and animals.

Context

9Àwọn ọmọ Israẹli sì mú gbogbo obìnrin Midiani ní ìgbèkùn àti àwọn ọmọ kékeré wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ẹrù wọn. 10Wọ́n finá jó gbogbo ìlú wọn àti ibùdó wọn. 11Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran. 12Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mose àti Eleasari àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Israẹli ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani létí Jeriko. 13Mose, Eleasari àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbèríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.