Native Bible

Numbers 30:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró.

Numbers 30:11 in English

Numbers 30:11 · Berean Standard Bible

and her husband hears of it but says nothing to her and does not prohibit her, then all the vows or pledges by which she has bound herself shall stand.

Context

9“Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀. 10“Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra, 11tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró. 12Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tú u sílẹ̀. 13Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúra ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.