Native Bible

Numbers 30:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra,

Numbers 30:10 in English

Numbers 30:10 · Berean Standard Bible

If a woman in her husband’s house has made a vow or put herself under an obligation with an oath,

Context

8Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjì í. 9“Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀. 10“Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra, 11tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró. 12Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tú u sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.