Numeri 3:41
Numbers 3:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí o sì gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa.”
Numbers 3:41 in English
Numbers 3:41 · Berean Standard Bible
You are to take the Levites for Me—I am the LORD—in place of all the firstborn of Israel, and the livestock of the Levites in place of all the firstborn of the livestock of the Israelites.”
Context
39Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Lefi tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose àti Aaroni gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000). 40Olúwa sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn. 41Kí o sì gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa.” 42Mose sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un. 43Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ọ̀rìnlúgba ó dín méje (22,273).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.