Numeri 3:39
Numbers 3:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Lefi tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose àti Aaroni gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000).
Numbers 3:39 in English
Numbers 3:39 · Berean Standard Bible
The total number of Levites that Moses and Aaron counted by their clans at the LORD’s command, including all the males a month old or more, was 22,000.
Context
37Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn. 38Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀-oòrùn níwájú àgọ́ ìpàdé.
Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli.
Àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á. 39Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Lefi tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose àti Aaroni gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000). 40Olúwa sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn. 41Kí o sì gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.