Numeri 28:14
Numbers 28:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òsùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún.
Numbers 28:14 in English
Numbers 28:14 · Berean Standard Bible
Their drink offerings shall be half a hin of wine * with each bull, a third of a hin * with the ram, and a quarter hin with each lamb. This is the monthly burnt offering to be made at each new moon throughout the year.
Context
12Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ ẹbọ ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ pẹ̀lú òróró; pẹ̀lú àgbò, ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ tí í ṣe ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ mọ́ òróró; 13pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná. 14Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òsùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún. 15Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 16“ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.