Native Bible

Numbers 28:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

Numbers 28:15 in English

Numbers 28:15 · Berean Standard Bible

In addition to the regular burnt offering with its drink offering, one male goat is to be presented to the LORD as a sin offering.

Context

13pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná. 14Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òsùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún. 15Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 16“ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé. 17Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.