Numeri 23:25
Numbers 23:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Balaki wí fún Balaamu pé, “O kò kúkú fi wọ́n bú, bẹ́ẹ̀ ni o kò súre fún wọn rárá!”
Numbers 23:25 in English
Numbers 23:25 · Berean Standard Bible
Now Balak said to Balaam, “Then neither curse them at all nor bless them at all!”
Context
23Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jakọbu,
tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Israẹli.
Nísinsin yìí a ó sọ nípa ti Jakọbu
àti Israẹli, ‘Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe!’ 24Àwọn ènìyàn náà yóò dìde bí abo kìnnìún;
wọ́n yóò sì gbé ara wọn sókè bí i kìnnìún
òun kì yóò sì dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ohun ọdẹ
títí yóò sì fi mu nínú ẹ̀jẹ̀ ohun pípa.” 25Nígbà náà ni Balaki wí fún Balaamu pé, “O kò kúkú fi wọ́n bú, bẹ́ẹ̀ ni o kò súre fún wọn rárá!” 26Balaamu dáhùn ó sì wí fún Balaki pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ha ti wí fún ọ pé, gbogbo èyí tí Olúwa bá sọ, òun ni èmi yóò ṣe?” 27Nígbà náà Balaki sọ fún Balaamu pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.