Numeri 23:22
Numbers 23:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.
Numbers 23:22 in English
Numbers 23:22 · Berean Standard Bible
God brought them out of Egypt with strength like a wild ox.
Context
20Èmi gba àṣẹ láti bùkún;
Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà. 21“Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jakọbu,
kò sì rí búburú kankan nínú Israẹli.
Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn.
Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn. 22Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá,
wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà. 23Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jakọbu,
tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Israẹli.
Nísinsin yìí a ó sọ nípa ti Jakọbu
àti Israẹli, ‘Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe!’ 24Àwọn ènìyàn náà yóò dìde bí abo kìnnìún;
wọ́n yóò sì gbé ara wọn sókè bí i kìnnìún
òun kì yóò sì dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ohun ọdẹ
títí yóò sì fi mu nínú ẹ̀jẹ̀ ohun pípa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.