Numeri 23:11
Numbers 23:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan, ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”
Numbers 23:11 in English
Numbers 23:11 · Berean Standard Bible
Then Balak said to Balaam, “What have you done to me? I brought you here to curse my enemies, and behold, you have only blessed them!”
Context
9Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn,
láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n.
Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀
wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè. 10Ta ni ó lè ka eruku Jakọbu
tàbí ka ìdámẹ́rin Israẹli?
Jẹ́ kí èmi kú ikú olódodo,
kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dà bí tirẹ̀!” 11Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan, ṣùgbọ́n o bùkún wọn!” 12Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?” 13Nígbà náà Balaki sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.