Numeri 22:17
Numbers 22:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára, èmi yóò sì ṣe ohunkóhun tí ìwọ bá sọ. Wá, kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.”
Numbers 22:17 in English
Numbers 22:17 · Berean Standard Bible
for I will honor you richly and do whatever you say. So please come and put a curse on this people for me!’”
Context
15Nígbà náà Balaki rán àwọn ìjòyè mìíràn tí wọ́n pọ̀ àwọn tí wọ́n sì níyì ju alákọ́kọ́ lọ. 16Wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu wọ́n sì sọ pé,
“Èyí ni ohun tí Balaki ọmọ Sippori sọ, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun kí ó dè ọ́ lọ́nà láti wá sí ọ̀dọ̀ mi, 17nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára, èmi yóò sì ṣe ohunkóhun tí ìwọ bá sọ. Wá, kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.” 18Ṣùgbọ́n Balaamu dá wọn lóhùn pé, “Kódà tí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò ní ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí ó kọjá òfin Olúwa Ọlọ́run mi. 19Nísinsin yìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí Olúwa yóò tún sọ fún mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.