Native Bible

Numbers 22:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Balaamu dá wọn lóhùn pé, “Kódà tí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò ní ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí ó kọjá òfin Olúwa Ọlọ́run mi.

Numbers 22:18 in English

Numbers 22:18 · Berean Standard Bible

But Balaam replied to the servants of Balak, “If Balak were to give me his house full of silver and gold, I could not do anything small or great to go beyond the command of the LORD my God.

Context

16Wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu wọ́n sì sọ pé, “Èyí ni ohun tí Balaki ọmọ Sippori sọ, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun kí ó dè ọ́ lọ́nà láti wá sí ọ̀dọ̀ mi, 17nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára, èmi yóò sì ṣe ohunkóhun tí ìwọ bá sọ. Wá, kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.” 18Ṣùgbọ́n Balaamu dá wọn lóhùn pé, “Kódà tí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò ní ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí ó kọjá òfin Olúwa Ọlọ́run mi. 19Nísinsin yìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí Olúwa yóò tún sọ fún mi.” 20Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Balaamu wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.