Numeri 21:20
Numbers 21:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àti láti Bamoti lọ sí àfonífojì ní Moabu níbi tí òkè Pisga, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí aginjù.
Numbers 21:20 in English
Numbers 21:20 · Berean Standard Bible
and from Bamoth to the valley in Moab where the top of Pisgah overlooks the wasteland.*
Context
18nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́,
nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ;
tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.”
Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana, 19láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti, 20àti láti Bamoti lọ sí àfonífojì ní Moabu níbi tí òkè Pisga, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí aginjù. 21Israẹli rán oníṣẹ́ láti sọ fún Sihoni ọba àwọn ará Amori wí pé, 22“Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.