Native Bible

Numbers 21:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́, nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ; tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.” Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana,

Numbers 21:18 in English

Numbers 21:18 · Berean Standard Bible

The princes dug the well; the nobles of the people hollowed it out with their scepters and with their staffs.” From the wilderness the Israelites went on to Mattanah,

Context

16Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.” 17Nígbà náà ni Israẹli kọ orin yìí pé, “Sun jáde, ìwọ kànga! Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀, 18nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́, nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ; tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.” Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana, 19láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti, 20àti láti Bamoti lọ sí àfonífojì ní Moabu níbi tí òkè Pisga, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí aginjù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.