Numeri 20:18
Numbers 20:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Edomu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun sí yín, a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”
Numbers 20:18 in English
Numbers 20:18 · Berean Standard Bible
But Edom answered, “You may not travel through our land, or we will come out and confront you with the sword.”
Context
16ṣùgbọ́n nígbà tí a sọkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán angẹli kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Ejibiti.
“Báyìí àwa wà ní Kadeṣi, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ. 17Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀-èdè rẹ kọjá, àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kànga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.” 18Ṣùgbọ́n Edomu dáhùn pé,
“Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun sí yín, a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.” 19Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé,
“A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkan kan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.” 20Wọ́n tún dáhùn wí pé,
“Ẹ kò lè kọjá.”
Nígbà náà ni Edomu jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ-ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.