Native Bible

Numbers 20:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí ni omi ti Meriba, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrín wọn.

Numbers 20:13 in English

Numbers 20:13 · Berean Standard Bible

These were the waters of Meribah,* where the Israelites quarreled with the LORD, and He showed His holiness among them.

Context

11Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu. 12Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.” 13Èyí ni omi ti Meriba, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrín wọn. 14Mose sì ránṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu, wí pé, “Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Israẹli sọ, ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa. 15Àwọn baba ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Ejibiti ni wá lára àti àwọn baba wa,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.