Native Bible

Numbers 20:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mose sì ránṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu, wí pé, “Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Israẹli sọ, ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa.

Numbers 20:14 in English

Numbers 20:14 · Berean Standard Bible

From Kadesh, Moses sent messengers to tell the king of Edom, “This is what your brother Israel says: You know all the hardship that has befallen us,

Context

12Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.” 13Èyí ni omi ti Meriba, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrín wọn. 14Mose sì ránṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu, wí pé, “Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Israẹli sọ, ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa. 15Àwọn baba ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Ejibiti ni wá lára àti àwọn baba wa, 16ṣùgbọ́n nígbà tí a sọkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán angẹli kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Ejibiti. “Báyìí àwa wà ní Kadeṣi, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.