Native Bible

Numbers 14:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi.

Numbers 14:34 in English

Numbers 14:34 · Berean Standard Bible

In keeping with the forty days you spied out the land, you shall bear your guilt forty years—a year for each day—and you will experience My alienation.

Context

32Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní aginjù yìí. 33Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú aginjù fun ogójì ọdún wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní aginjù. 34Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi. 35Èmi, Olúwa, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kó ra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú aginjù yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.” 36Àwọn ọkùnrin tí Mose rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú gbogbo ìjọ kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.