Native Bible

Numbers 14:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọkùnrin tí Mose rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú gbogbo ìjọ kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà;

Numbers 14:36 in English

Numbers 14:36 · Berean Standard Bible

So the men Moses had sent to spy out the land, who had returned and made the whole congregation grumble against him by bringing out a bad report about the land—

Context

34Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi. 35Èmi, Olúwa, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kó ra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú aginjù yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.” 36Àwọn ọkùnrin tí Mose rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú gbogbo ìjọ kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà; 37Olúwa sì kọlu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀-ààrùn sì pa wọ́n níwájú Olúwa. 38Nínú gbogbo àwọn tó lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne ló yè é.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.