Native Bible

Numbers 14:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú aginjù fun ogójì ọdún wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní aginjù.

Numbers 14:33 in English

Numbers 14:33 · Berean Standard Bible

Your children will be shepherds in the wilderness for forty years, and they will suffer for your unfaithfulness until the last of your bodies lies in the wilderness.

Context

31Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀sílẹ̀. 32Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní aginjù yìí. 33Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú aginjù fun ogójì ọdún wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní aginjù. 34Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi. 35Èmi, Olúwa, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kó ra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú aginjù yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.