Native Bible

Numbers 12:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe, ó rí àwòrán Olúwa. Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?”

Numbers 12:8 in English

Numbers 12:8 · Berean Standard Bible

I speak with him face to face, clearly and not in riddles; he sees the form of the LORD. Why then were you unafraid to speak against My servant Moses?”

Context

6Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, “Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrín yín, Èmi Olúwa a máa fi ara à mi hàn án ní ojúran, Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá. 7Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mose ìránṣẹ́ mi; ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo ilé mi. 8Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe, ó rí àwòrán Olúwa. Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?” 9Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀. 10Nígbà tí ìkùùkuu kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Miriamu di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Aaroni sì padà wo Miriamu ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.