Numeri 12:7
Numbers 12:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mose ìránṣẹ́ mi; ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo ilé mi.
Numbers 12:7 in English
Numbers 12:7 · Berean Standard Bible
But this is not so with My servant Moses; he is faithful in all My house.*
Context
5Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ́n ìkùùkuu, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Aaroni àti Miriamu. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú, 6Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,
“Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrín yín,
Èmi Olúwa a máa fi ara à mi hàn án ní ojúran,
Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá. 7Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mose ìránṣẹ́ mi;
ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo ilé mi. 8Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,
ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe,
ó rí àwòrán Olúwa.
Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù
láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?” 9Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.