Native Bible

Numbers 11:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọ̀ sánmọ̀ ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́.

Numbers 11:25 in English

Numbers 11:25 · Berean Standard Bible

Then the LORD came down in the cloud and spoke to him, and He took some of the Spirit that was on Moses and placed that Spirit on the seventy elders. As the Spirit rested on them, they prophesied—but they never did so again.

Context

23Olúwa sì dá Mose lóhùn pé, “Ọwọ́ Olúwa ha kúrú bí? Ìwọ yóò ri nísinsin yìí bóyá ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò ṣẹ tàbí kò ni í ṣẹ.” 24Mose sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin àgbàgbà Israẹli dúró yí àgọ́ ká. 25Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọ̀ sánmọ̀ ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́. 26Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Eldadi àti Medadi kò kúrò nínú àgọ́. Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin àgbàgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ síbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́. 27Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mose pé, “Eldadi àti Medadi ń sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.