Native Bible

Numbers 11:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mose sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin àgbàgbà Israẹli dúró yí àgọ́ ká.

Numbers 11:24 in English

Numbers 11:24 · Berean Standard Bible

So Moses went out and relayed to the people the words of the LORD, and he gathered seventy of the elders of the people and had them stand around the tent.

Context

22Ǹjẹ́ bí a tilẹ̀ pa àgbò ẹran àti ọmọ ẹran, yóò ha tó wọn bí? Tàbí bí a tilẹ̀ pa gbogbo ẹja inú omi fún wọn, yóò wa tó bí?” 23Olúwa sì dá Mose lóhùn pé, “Ọwọ́ Olúwa ha kúrú bí? Ìwọ yóò ri nísinsin yìí bóyá ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò ṣẹ tàbí kò ni í ṣẹ.” 24Mose sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin àgbàgbà Israẹli dúró yí àgọ́ ká. 25Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọ̀ sánmọ̀ ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́. 26Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Eldadi àti Medadi kò kúrò nínú àgọ́. Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin àgbàgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ síbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.