Numeri 11:27
Numbers 11:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mose pé, “Eldadi àti Medadi ń sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.”
Numbers 11:27 in English
Numbers 11:27 · Berean Standard Bible
A young man ran and reported to Moses, “Eldad and Medad are prophesying in the camp.”
Context
25Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọ̀ sánmọ̀ ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́. 26Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Eldadi àti Medadi kò kúrò nínú àgọ́. Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin àgbàgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ síbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́. 27Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mose pé, “Eldadi àti Medadi ń sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.” 28Joṣua ọmọ Nuni tí í ṣe ìránṣẹ́ Mose, láti kékeré tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dáhùn pé, “Mose olúwa mi, dá wọn lẹ́kun!” 29Mose sì wí fún un pé, “Àbí ìwọ ń jowú nítorí mi? Ìbá ti wù mí tó, kí gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa jẹ́ wòlíì, kí Olúwa sì fi Ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.