Native Bible

Numbers 11:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán,

Numbers 11:19 in English

Numbers 11:19 · Berean Standard Bible

You will eat it not for one or two days, nor for five or ten or twenty days,

Context

17Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú díẹ̀ nínú agbára Ẹ̀mí tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà. 18“Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Ejibiti jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́. 19Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán, 20ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan, títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrín yín, ẹ sì ti sọkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ejibiti gan an?” ’ ” 21Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Mo wà láàrín ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn (600,000) ni ìrìnkiri, ó sì sọ pé, ‘Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko!’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.